Skip to content

Matters Arising

Beautiful Nubia, the Roots Renaissance Band
Popularity · Low

YouTube

Searching YouTube...

Lyrics

E a ma de o, a ma de o A wa nk'ilo fun'ra wa ni o E a ma de o, a ma de o E je a s'otito fun'rawa o Iwo gb'esin s'ori, gbogbo ara ilu ti wa d'elese loju e Eyin gbesin s'ori, e wa npa'niyan l'oruko Olorun l'oke Se iwo ti gbagbe P'Olorun oba, Olorun ife ni kii korira Se eyin ti gbage p'Eledumare alagbara O le gbe'ja ara re Iwo de'po ola, o wa nsi'wa wu, o ti gbagbe orisun On j'aye olowo, omode ilu nwo'nu akitan k'ebi ma pa won o Ko le s'alaafia ninu ilu b'inu ara ilu o ba dun Ko le s'alaafia f'olowo fun talaka Ba o ba s'otito n'ijoba o Ore otito s'owon o Ife otito s'owon ye Oo le gb'ara l'enikankan o Won a ba e je o, won a ba e mu o To ba y'eyin pada, won a s'oro e ni buruku Won a ba e l'ogba, won a ba e je'gbadun B'igba ba yi pere gbogbo won a sa lo o Ilara ti poju, ikorira ti poju Ko le s'ilosiwaju ninu abosi Ikunsinu ti poju at'imoteni nikan Ko le s'ilosiwaju ninu iwa ibaje yi o